Call Us Now :

08078615503

SHOPPING CART

Your Cart is empty

FUNNAB


IṢẸ́ ÒGBÌN TỌ́ṢẸMÚDÚRÓPẸ́ a. Ìlànà òg̣bìn tó dáára (GAP) àti Ìlànà òg̣bìn tó jáfáfá (SAP)
b. Ìsàmúdóg̣ba Ìyípadà ojú-ọjọ́ nípasẹ̀ GAP àti SAP

Victor Olowe & John Oyedepo
Institute of Food Security, Environmental Resources and Agricultural Research (IFSERAR),
Federal University of Agriculture, Abeokuta, Nigeria.

ILANA
A: IFAARA
B: AWỌN IṢE ÒGBÌN TÓ DARA
C: AWỌN IṢE ÒGBÌN TÓ JÁFÁFÁ
D: ÌSÀMÚDỌ́GBA ÌYÍPADÀ OJÚ-ỌJỌ NÍPASẸ̀ GAP/SAP
E: ÌDÁÀBÒ

A: IFAARA
• Ni gbogbo agbaiye, iṣẹ́ agbẹ̀ maa ń kó oju àwọn ìpẹ̀njá oju-ọjọ tó sì maa ń ṣe àkóbá fún àwọn irè oko.
• Ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú jẹ́ ẹni tó ní ipalara jùlọ nípa ayipada oju-ọjọ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ní àfikún ìwọ̀n gbígbóná tàbí òtútù.
• Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipalara tó pọ̀ ni àwọn ayipada oju-ọjọ, ìdá mẹ́rin (4%) nínú ọgọ́rùn-ún ni owó ìṣúná afẹ́fẹ́ àgbáyé tí ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú rí gba nígbà tó sì jẹ́ pé $3 trillion ni wọ́n nílò fún ìgbésẹ̀ láti koju ìyípadà oju-ọjọ.

Ogoji (40m) nínú ọgọ́rùn-ún mẹ́tadínlọ́gọ́rin (91m) ìwọ̀n ilẹ̀ ni wọ́n ti lò fún ogbin.
• Ilẹ̀ jẹ́ ohun èlò pàtàkì fún iṣẹ́ ogbin ní ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú.
• Àkànṣe ilẹ̀ tí a ṣe àgbékálẹ̀ fún ènìkọ̀ọ̀kan fún iṣẹ́ agbẹ̀ jẹ́ 2,100 m² pẹ̀lú ìròyìn pé ènìkọ̀ọ̀kan yóò ní ìwọ̀n ilẹ̀ 504 m² ní ọdún 2100.
• Ìye àwọn ènìyàn tó fojú sójú pé ní ọdún 2100 yóò tó 88 milionu (Hoornweg & Pope, 2017).
• Bí 116.1g èso àti ewé bẹ́ẹ̀ ni ó wà fún ènìkọ̀ọ̀kan dípò 400g tí WHO dá lórí (Olowe, 2021).
• Nítorí èyí, a nílò iṣẹ́ ogbin tó ṣèmúdùró pẹ̀lú ìmọ̀lára.

KINI IṢẸ́ AGBẸ̀ TÓ ṢÈMÚDÙRÓPẸ́?
Gẹ́gẹ́ bí USDA (1977): Ètò ogbin àti ọ̀sìn aláṣepọ̀ ní ìlànà tí yóò jẹ́ kí oúnjẹ wà lọ́pọ̀, kí ó lè t’ẹni lórun àti pèsè okun (fibre) fún ìwúlò ènìyàn láì ṣe ìdíbàjẹ́ fún ohun alumọ́ni ilẹ̀ àti ilera ayé.

B: AWỌN IṢE ÒGBÌN TÓ DARA (GAP)
• Ìmúṣẹ́ iṣẹ́ ogbin tó dára lè mú agbára iṣẹ́ ogbin àti ọ̀sìn pọ̀ síi pẹ̀lú ìgbòòrò ajé.
• Àpẹẹrẹ irúgbìn: Lílò ìwọnba àpọ̀pọ̀ ajile ní àkókò tó yẹ, fífi ìgbẹ́ màálúù tàbí ajile míì fún ìtọju ìlera ilẹ̀ àti fífi èbè sí ẹ̀gbẹ́ gbogbo pápá.

C: AWỌN IṢE ÒGBÌN TÓ JÁFÁFÁ (SAP)
• Ṣíṣàkóso ilẹ̀, irúgbìn, ọ̀sìn àti igi láti dín ipa ìyípadà oju-ọjọ kù.
• Ọ̀nà mẹ́ta pàtàkì: Ere oko, Àṣàmúlò dọ́gbà, Ìdínkù eéfín.

ÀWỌN ÀPẸ̀RẸ:
i. Gbígbìn ohun ogbin oríṣìíríṣìí tí afẹ́fẹ́ kò lè ba jẹ́.
ii. Eto yíyí irúgbìn padà.
iii. Iṣakoso kokoro àti arun.
iv. Ìṣàkóso omi.
v. Gbígbìn igi.

ANFANI YIYÍ IRÚGBÌN PADÀ
• Mu ìlera ilẹ̀ dara
• Dín ìfarapa kokoro kù
• Ṣe àfọ̀mọ́ agbẹ̀ nípa lílo ajile adayeba

E: ÌMÒRAN ÀMÚLÒ
• Àwọn agbẹ̀ gbọ́dọ̀ mura sílẹ̀ láti gba ìmòran lori bi oju-ọjọ ṣe lè nípa lórí iṣẹ́ wọn.
• Ifowosowopo pẹ̀lú àwọn amọ̀ràn, onímọ̀ ojú-ọjọ àti alákóso agbègbè jẹ́ pàtàkì.
• Lílò owó ìdàgbàsókè láti ACCF, CIF, GEF àti Green Climate Fund.

E ṢE ADÚPẸ́ FÚN ÌTẸ̀TÌSÍLẸ̀

Subscribe To Our Newsletter

Get all the latest information on Events, Sales and Offers.