Call Us Now :

08078615503

SHOPPING CART

Your Cart is empty

FUNNAB

Ipà ìmúdàgbà Ẹgbẹ́ Aláfọwósowọ́pọ̀ fún Iṣẹ́ Ògbìn Alásepẹ́

Ògbìn Alásepé
Ohun tó jẹ́ ògbìn alásepé ni òògùn ìdábòbò ayé, ìbáṣepọ̀ ènìyàn láàrin àwùjọ, ọ̀rọ̀ ajé tó péye, ìtọ́jú àwọn ohun alumọ́ni láti pèsè àwọn àìní eto onjẹ lọwọlọwọ láì ṣe ipalara fún eto àwọn àìní ọjọ́ iwájú.
Kò sí bí àwọn ìmọ̀ tuntun tàbí ìmọ̀ ẹ̀rọ ṣe lè dára tó, àjọmọ́ ni ìpinnu àwọn ènìyàn máa sábà jẹ́, nítorí wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ ara wọn kí wọ́n tó pinnu.

Ìpàràpọ̀ ìmúdàgbà àjọṣe ẹgbẹ́ àti Ògbìn Alásepé
Tí ìtànkálẹ̀ ìmọ̀ tuntun bá máa yara, gbooro àti jìǹlẹ̀, ìbáṣepọ̀ àti ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kò ṣe é má ṣe. Ìlọsíwájú ìmọ̀ tuntun kò ṣe yà sọ́tọ̀.

Àwọn Ànfààní

  • Wiwọlé tídára sí ògbìn tàbí àwọn ọ̀nà ẹ̀rọ ìkọ́ré tó pọ̀, yanturu àti púpọ̀ ẹ̀rè

  • Aṣojú àkójọpọ̀

  • Àlẹ̀kùn agbára ìdúnàdúrà

  • Ìlálùjá fún ọjà ohun ògbìn wa

  • Ànfààní àti yá owó ìdókòwò

  • Pínpín ìmọ̀ kún ìmọ̀

Àpẹ̀júwe Ẹgbẹ́
Ẹgbẹ́ jẹ́ àpẹ̀jọpọ̀ ènìyàn méjì tàbí ju bẹ́ lọ, tí èrò wọn papọ̀, tí wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣàṣeyọrí nínú ibi-afẹ́de tó pa wọn pọ̀. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ara wọn nítorí ọ̀pọ̀ àwọn nkan bí ìgbọ́kànlé tí a pin, ìrètí, àti àwọn ìlànà.
Ẹgbẹ́ gbọ́dọ̀ pàdé ara wọn – ní ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìbáṣepọ̀ – kí wọ́n lè ní ipa.

Fún ẹgbẹ́ láti munadoko:

  • Ẹgbẹ́ pipe yẹ kí ó jẹ́ kékeré àti ìsokan.

  • Ibi-afẹ́de àti àwọn ànfààní yẹ kí ó jẹ́ kedere.

  • Àwọn ẹgbẹ́ yẹ kí ó jẹ́ tiwántíwá àti atinuwa.

Kí ni ìmúdàgbà ẹgbẹ́?
Àwọn ìwádìí nípa bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe hùwà àti bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Tí tẹ̀jumọ̀ ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́, bí ẹgbẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́, àti ipa tí ẹnikẹ́ni ní nínú ìdàgbàsókè ẹgbẹ́. Àwọn ìgbésẹ̀ àti ìlànà inú ọkàn tó ń wáyé láàrin ẹgbẹ́ àwùjọ ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí agbára ìmúdàgbà ẹgbẹ́.

Olúkúlùkù oríṣìíríṣìí ènìyàn nínú ẹgbẹ́:

  • Alákojọpọ̀ alatuntọ: Ọmọ ẹgbẹ́ kan tí ó ń gbìyànjú láti ṣètọju ìsokan – a mọ̀ ọ́ sí ìbáramu, tàbí olùwá àlàáfíà. Nígbà tí àríyànjiyàn bá wà, ẹni yìí máa ń gbìyànjú láti làjà.

  • Olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà: Ẹni tó ń ṣiṣẹ́ láti gbé àwọn míì ga, kó jẹ́ kí wọ́n ní ìṣọkan, àti kó dáwọ̀ àwọn t’ó wá láti òde dúró.

  • Olùtẹ̀lé: Ẹni tó ń gba sí ohun gbogbo tí àwọn míì pinnu.

  • Onínú fùfù: Ẹni tó ń ṣòfíntóró ẹgbẹ́ tàbí ohun gbogbo tí ẹgbẹ́ ń gbìyànjú.

  • Adínilówó: Ẹni tó ń lòdì sí àwọn ìpinnu láìnídí, tó máa ń ṣiṣẹ́ láti jẹ́ kó má ṣàṣeyọrí.

  • Ajẹ́gàbà: Ẹni tó ń ṣe àkọ́so ohun gbogbo, tó ń lo àṣẹ àti tó ń ṣàtẹ̀wọ̀n àwọn míì.

  • Olùṣètò pipe: Ẹni tó ń fi àpẹẹrẹ hàn ní iṣẹ́, ìhuwasi tàbí iye, tó ní ipa lórí àwọn míì nípasẹ̀ ìṣe rẹ̀, àṣẹ tàbí ìmọ̀ rẹ̀.

Tuckman’s Model:

  1. Ẹgbẹ́ wá papọ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣàfihàn ara wọn.

  2. Àríyànjiyàn lè dide bí wọ́n ṣe ń ṣètò ipa wọn.

  3. Ẹgbẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í yanju ìyàtọ̀, ṣiṣẹ́da ìsòmọ́.

  4. Ẹgbẹ́ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbára sí ibi-afẹ́de.

  5. Ẹgbẹ́ tú káwọn iṣẹ́ rẹ̀ bá parí.

Kẹ̀kẹ́ ti Group Dynamics:

  • Ìṣọkan ẹgbẹ́

  • Rogbodiyan jẹ́ ohun tí a kò lè yà sílẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣe àjọṣepọ̀. Ìyàtọ̀ nínú èrò, ìwà, ohun tí jẹ́ ti olukúlùkù ló sábà ń fa rogbodiyan.

  • Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ – “Méjì dára jù ọ̀kan lọ.”

  • Gbígbà ara ẹni mọ́ra: jẹ́ olùrànlọ́wọ́, jẹ́ onínúure, pa ọ̀tá pẹ̀lú inú-rere.

  • Ìyẹ́ra fún: Nígbà gbogbo papọ̀, láìlàyàtọ̀ sí ilérí ẹni.

  • Yíyàn dá: Má gba gbogbo rẹ̀, fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ẹgbẹ́ méjèèjì.

Àwọn Okùnfa Ìṣọkan Ẹgbẹ́:

  • Ìwọn ẹgbẹ́: gbọ́dọ̀ kékeré

  • Ìbáṣepọ̀: gbọ́dọ̀ pọ̀ dáadáa

  • Idíje pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ mìíràn

  • Àwọn ìrírí tó dùn

Ìdínkù àwọn okùnfa:

  • Tóbi → kékeré

  • Idíje láàrin ọmọ ẹgbẹ́

  • Ìrírí búburú

Subscribe To Our Newsletter

Get all the latest information on Events, Sales and Offers.